۞ وَاِنْ جَنَحُوْا لِلسَّلْمِ فَاجْنَحْ لَهَا وَتَوَكَّلْ عَلَى اللّٰهِ ۗاِنَّهٗ هُوَ السَّمِيْعُ الْعَلِيْمُ
wa in janaḥū lis-salmi fajnaḥ lahā wa tawakkal ‘alallāh(i), innahū huwas-samī‘ul-‘alīm(u).
Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá fẹ́ sí àlàáfíà, gbà á, kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Allāhu. Dájúdájú, Òun ni Olùgbọ́ gbogbo nǹkan, Olùmọ̀ gbogbo nǹkan.
اِلَّا الَّذِيْنَ عَاهَدْتُّمْ مِّنَ الْمُشْرِكِيْنَ ثُمَّ لَمْ يَنْقُصُوْكُمْ شَيْـًٔا وَّلَمْ يُظَاهِرُوْا عَلَيْكُمْ اَحَدًا فَاَتِمُّوْٓا اِلَيْهِمْ عَهْدَهُمْ اِلٰى مُدَّتِهِمْۗ اِنَّ اللّٰهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِيْنَ
illal-lażīna ‘āhattum minal-musyrikīna ṡumma lam yanquṣūkum syai'aw wa lam yuẓāhirū ‘alaikum aḥadan fa atimmū ilaihim ‘ahdahum ilā muddatihim, innallāha yuḥibbul-muttaqīn(a).
Àyàfi àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n ti bá ọ ṣe àdéhùn tí wọn kò sì dín (àkóónú àdéhùn náà) kù rárá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó lòdì sí ọ, lẹ́yìn náà, wọ́n mú ìlérí wọn ṣẹ títí di àsìkò tí ó yẹ. Dájúdájú, Allāhu fẹ́ràn àwọn olùbẹ̀rù.