اَللّٰهُ الَّذِيْ رَفَعَ السَّمٰوٰتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا ثُمَّ اسْتَوٰى عَلَى الْعَرْشِ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَۗ كُلٌّ يَّجْرِيْ لِاَجَلٍ مُّسَمًّىۗ يُدَبِّرُ الْاَمْرَ يُفَصِّلُ الْاٰيٰتِ لَعَلَّكُمْ بِلِقَاۤءِ رَبِّكُمْ تُوْقِنُوْنَ
allāhul-lażī rafa‘as-samāwāti bigairi ‘amadin taraunahā ṡummastawā ‘alal-‘arsyi wa sakhkharasy-syamsa wal-qamar(a), kulluy yajrī li'ajalim musammā(n), yudabbirul-amra yufaṣṣilul-āyāti la‘allakum biliqā'i rabbikum tūqinūn(a).
Allah gbé àwọn ọ̀run sókè láìsí àwọn òpó (bí) tí ẹ rí, lẹ́yìn náà Ó jókòó lórí ìtẹ́. Ó tẹ oòrùn àti òṣùpá ba; ọ̀kọ̀ọ̀kan ń yípo gẹ́gẹ́ bí àkókò tí a ti yàn kalẹ̀. Ó ń ṣètò àwọn ọ̀ràn (ẹ̀dá Rẹ̀), Ó sì ń ṣàlàyé àwọn àmì (títóbi Rẹ̀), kí ẹ lè ní ìdánilójú pé ẹ máa pàdé Olúwa yín.
وَسَخَّرَ لَكُمُ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ دَاۤىِٕبَيْنِۚ وَسَخَّرَ لَكُمُ الَّيْلَ وَالنَّهَارَ ۚ
wa sakhkhara lakumusy-syamsa wal-qamara dā'ibaīn(i), wa sakhkhara lakumul-laila wan-nahār(a).
Ó sì ti fi oòrùn àti òṣùpá fún yín, wọ́n ń yípo nígbà gbogbo (nínú àyíká wọn); Ó sì ti fi òru àti ọ̀sán fún yín.
وَسَخَّرَ لَكُمُ الَّيْلَ وَالنَّهَارَۙ وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۗوَالنُّجُوْمُ مُسَخَّرٰتٌۢ بِاَمْرِهٖ ۗاِنَّ فِيْ ذٰلِكَ لَاٰيٰتٍ لِّقَوْمٍ يَّعْقِلُوْنَۙ
wa sakhkhara lakumul-laila wan-nahār(a), wasy-syamsa wal-qamar(a), wan-nujūmu musakhkharātum bi'amrih(ī), inna fī żālika la'āyātil liqaumiy ya‘qilūn(a).
Ó fi òru àti ọ̀sán, oòrùn àti òṣùpá lé yín lọ́wọ́, àti pé àṣẹ Rẹ̀ ni ó ń darí àwọn ìràwọ̀. Dájúdájú, nínú èyí ni àwọn àmì (títóbi Allāhu) wà fún àwọn tí ó ní òye.
وَجَعَلْنَا الَّيْلَ وَالنَّهَارَ اٰيَتَيْنِ فَمَحَوْنَآ اٰيَةَ الَّيْلِ وَجَعَلْنَآ اٰيَةَ النَّهَارِ مُبْصِرَةً لِّتَبْتَغُوْا فَضْلًا مِّنْ رَّبِّكُمْ وَلِتَعْلَمُوْا عَدَدَ السِّنِيْنَ وَالْحِسَابَۗ وَكُلَّ شَيْءٍ فَصَّلْنٰهُ تَفْصِيْلًا
wa ja‘alnal-laila wan-nahāra āyataini fa maḥaunā āyatal-laili wa ja‘alnā āyatan-nahāri mubṣiratal litabtagū faḍlam mir rabbikum wa lita‘lamū ‘adadas-sinīna wal-ḥisāb(a), wa kulla syai'in faṣṣalnāhu tafṣīlā(n).
A sì ṣe òru àti ọ̀sán ní àmì méjì (títóbi wa), lẹ́yìn náà A pa àmì òru náà rẹ́, A sì sọ àmì ọ̀sán di ìmọ́lẹ̀, kí ẹ lè wá oore-ọ̀fẹ́ lọ́dọ̀ Olúwa yín, kí ẹ sì lè mọ iye ọdún àti ìṣírò (àkókò). A sì ti ṣàlàyé gbogbo nǹkan ní kedere.
وَلَبِثُوْا فِيْ كَهْفِهِمْ ثَلٰثَ مِائَةٍ سِنِيْنَ وَازْدَادُوْا تِسْعًا
wa labiṡū fī kahfihim ṡalāṡa mi'atin sinīna wazdādū tis‘ā(n).
Wọ́n sì gbé inú ihò náà fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún pẹ̀lú ọdún mẹ́sàn-án.