اِنَّمَا الْمُؤْمِنُوْنَ الَّذِيْنَ اٰمَنُوْا بِاللّٰهِ وَرَسُوْلِهٖ وَاِذَا كَانُوْا مَعَهٗ عَلٰٓى اَمْرٍ جَامِعٍ لَّمْ يَذْهَبُوْا حَتّٰى يَسْتَأْذِنُوْهُۗ اِنَّ الَّذِيْنَ يَسْتَأْذِنُوْنَكَ اُولٰۤىِٕكَ الَّذِيْنَ يُؤْمِنُوْنَ بِاللّٰهِ وَرَسُوْلِهٖۚ فَاِذَا اسْتَأْذَنُوْكَ لِبَعْضِ شَأْنِهِمْ فَأْذَنْ لِّمَنْ شِئْتَ مِنْهُمْ وَاسْتَغْفِرْ لَهُمُ اللّٰهَ ۗاِنَّ اللّٰهَ غَفُوْرٌ رَّحِيْمٌ
innamal-mu'minūnal-lażīna āmanū billāhi wa rasūlihī wa iżā kānū ma‘ahū ‘alā amrin jāmi‘il lam yażhabū ḥattā yasta'żinūh(u), innal-lażīna yasta'żinūnaka ulā'ikal-lażīna yu'minūna billāhi wa rasūlih(ī), fa iżasta'żanūka liba‘ḍi sya'nihim fa'żal liman syi'ta minhum wastagfir lahumullāh(a), innallāha gafūrur raḥīm(un).
Àwọn tí a pè ní onígbàgbọ́ nìkan ni àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (Muhammad), nígbà tí wọ́n bá sì wà pẹ̀lú rẹ̀ (Muhammad) nínú ọ̀rọ̀ kan náà, wọn kò ní fi (Òjíṣẹ́ Ọlọ́run) sílẹ̀ kí wọ́n tó béèrè fún ìyọ̀ǹda rẹ̀. Dájúdájú, àwọn tí wọ́n ń béèrè ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ rẹ (Muhammad), àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn ènìyàn tí ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní òtítọ́. Nítorí náà, tí wọ́n bá béèrè ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ rẹ nítorí àìní kan, fún ẹni tí o bá fẹ́ láyè nínú wọn, kí o sì tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Allāhu fún wọn. Dájúdájú Allāhu jẹ́ Aláforíjìn, Àánú jùlọ.