لَا تَجْعَلُوْا دُعَاۤءَ الرَّسُوْلِ بَيْنَكُمْ كَدُعَاۤءِ بَعْضِكُمْ بَعْضًاۗ قَدْ يَعْلَمُ اللّٰهُ الَّذِيْنَ يَتَسَلَّلُوْنَ مِنْكُمْ لِوَاذًاۚ فَلْيَحْذَرِ الَّذِيْنَ يُخَالِفُوْنَ عَنْ اَمْرِهٖٓ اَنْ تُصِيْبَهُمْ فِتْنَةٌ اَوْ يُصِيْبَهُمْ عَذَابٌ اَلِيْمٌ
lā taj‘alū du‘ā'ar-rasūli bainakum kadu‘ā'i ba‘ḍikum ba‘ḍā(n), qad ya'lamullāhul-lażīna yatasallalūna minkum liwāżā(n), falyaḥżaril-lażīna yukhālifūna ‘an amrihī an tuṣībahum fitnatun au yuṣībahum ‘ażābun alīm(un).
Ẹ má ṣe pe ìpè Òjíṣẹ́ (Muhammad) láàrin yín gẹ́gẹ́ bí ìpè tí àwọn kan nínú yín ń pè sí àwọn mìíràn. Dájúdájú, Allāhu mọ àwọn tí ń jáde lọ ní ìkọ̀kọ̀ láàrín yín nípa gbígbà ààbò (nínú àwọn ọ̀rẹ́ wọn), nítorí náà, kí àwọn tí wọ́n bá rú àṣẹ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ bẹ̀rù pé wọn yóò dán wọn wò tàbí kí wọ́n lù wọ́n ní ìyà líle.
اِنَّ الَّذِيْنَ يُنَادُوْنَكَ مِنْ وَّرَاۤءِ الْحُجُرٰتِ اَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُوْنَ
innal-lażīna yunādūnaka miw warā'il-ḥujurāti akṡaruhum lā ya‘qilūn(a).
Lóòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń pè ọ́ (Muhammad) láti ìta yàrá (rẹ) kò lóye.
وَلَوْ اَنَّهُمْ صَبَرُوْا حَتّٰى تَخْرُجَ اِلَيْهِمْ لَكَانَ خَيْرًا لَّهُمْ ۗوَاللّٰهُ غَفُوْرٌ رَّحِيْمٌ
wa lau annahum ṣabarū ḥattā takhruja ilaihim lakāna khairal lahum, wallāhu gafūrur raḥīm(un).
Tí wọ́n bá sì ní sùúrù títí ìwọ yóò fi jáde wá pàdé wọn, ìbá dára jù fún wọn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àánú jùlọ.