99
Q.S Al-Mu'minun (23:99)
حَتّٰىٓ اِذَا جَاۤءَ اَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ رَبِّ ارْجِعُوْنِ ۙ
Ḥattā iżā jā'a aḥadahumul-mautu qāla rabbirji‘ūn(i).
(Bẹ́ẹ̀ ni ipò àwọn aláìgbàgbọ́ rí), títí tí ikú yóò fi dé bá ọ̀kan nínú wọn, yóò wí pé, “Olúwa mi, dá mi padà (sí ayé).
100
Q.S Al-Mu'minun (23:100)
لَعَلِّيْٓ اَعْمَلُ صَالِحًا فِيْمَا تَرَكْتُ كَلَّا ۗاِنَّهَا كَلِمَةٌ هُوَ قَاۤىِٕلُهَاۗ وَمِنْ وَّرَاۤىِٕهِمْ بَرْزَخٌ اِلٰى يَوْمِ يُبْعَثُوْنَ
la‘allī a‘malu ṣāliḥan fīmā taraktu kallā, innahā kalimatun huwa qā'iluhā, wa miw warā'ihim barzakhun ilā yaumi yub‘aṡūn(a).
kí n lè ṣe iṣẹ́ rere tí mo fi sílẹ̀.” Rárá o! Ní tòótọ́, àwáwí lásán ni èyí. Àti pé ó wà níwájú wọn títí di ọjọ́ tí wọ́n yóò jíǹde.