Q.S Al-Mujadilah (58:7)
اَلَمْ تَرَ اَنَّ اللّٰهَ يَعْلَمُ مَا فِى السَّمٰوٰتِ وَمَا فِى الْاَرْضِۗ مَا يَكُوْنُ مِنْ نَّجْوٰى ثَلٰثَةٍ اِلَّا هُوَ رَابِعُهُمْ وَلَا خَمْسَةٍ اِلَّا هُوَ سَادِسُهُمْ وَلَآ اَدْنٰى مِنْ ذٰلِكَ وَلَآ اَكْثَرَ اِلَّا هُوَ مَعَهُمْ اَيْنَ مَا كَانُوْاۚ ثُمَّ يُنَبِّئُهُمْ بِمَا عَمِلُوْا يَوْمَ الْقِيٰمَةِۗ اِنَّ اللّٰهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيْمٌ
alam tara annallāha ya‘lamu mā fis-samāwāti wa mā fil-arḍ(i), mā yakūnu min najwā ṡalāṡatin illā huwa rābi‘uhum wa lā khamsatin illā huwa sādisuhum wa lā adnā min żālika wa lā akṡara illā huwa ma‘ahum aina mā kānū, ṡumma yunabbi'uhum bimā ‘amilū yaumal-qiyāmah(ti), innallāha bikulli syai'in ‘alīm(un).
Ṣé o kò rí i pé Allāhu mọ ohun tí ó wà ní ọ̀run àti ohun tí ó wà ní ilẹ̀? Kò sí ìjíròrò ìkọ̀kọ̀ láàárín àwọn mẹ́ta ṣùgbọ́n Òun ni ẹ̀kẹrin nínú wọn. Kò sì sí márùn-ún ṣùgbọ́n Òun ni ẹ̀kẹfà. Kò sì sí ohun tí ó dín ju ìyẹn lọ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣùgbọ́n Ó wà pẹ̀lú wọn níbikíbi tí wọ́n bá wà. Lẹ́yìn náà Ó máa sọ fún wọn nípa ohun tí wọ́n ń ṣe ní ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo nǹkan.